Kronika Kinni 15:27-29 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Dafidi ati gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu, ati àwọn akọrin ati Kenanaya, olórí àwọn akọrin wọ aṣọ funfun tí ń dán, Dafidi sì wọ efodu funfun.

28. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli ṣe gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ìró orin ayọ̀, tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí ohun èlò orin bíi ipè, fèrè, aro, hapu ati dùùrù kọ.

29. Bí wọ́n ti ń gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wọ ìlú Dafidi, Mikali ọmọbinrin Saulu yọjú láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi tí ń jó, tí ń fò sókè tayọ̀tayọ̀, ó sì pẹ̀gàn rẹ̀ ninu ara rẹ̀.

Kronika Kinni 15