Kronika Kinni 12:19-30 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Àwọn kan ninu ẹ̀yà Manase darapọ̀ mọ́ Dafidi nígbà tí òun pẹlu àwọn ará Filistia wá láti bá Saulu jagun. (Sibẹsibẹ kò lè ran àwọn Filistia lọ́wọ́, nítorí pé lẹ́yìn tí àwọn ọba àwọn Filistini jíròrò láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ewu ń bẹ nítorí pé yóo darapọ̀ pẹlu Saulu, ọ̀gá rẹ̀.”) Wọ́n bá dá a pada lọ sí Sikilagi.

20. Bí ó ti ń pada lọ sí Sikilagi, àwọn ará Manase kan wá, wọ́n bá darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi. Orúkọ wọn ni: Adina, Josabadi, Jediaeli, ati Mikaeli; Josabadi, Elihu ati Siletai, olórí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ ogun ninu ẹ̀yà Manase.

21. Wọ́n ran Dafidi lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan, nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ akọni jagunjagun, wọ́n sì jẹ́ ọ̀gágun.

22. Lojoojumọ ni àwọn eniyan ń wá sọ́dọ̀ Dafidi láti ràn án lọ́wọ́; títí tí wọ́n fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n dàbí ogun ọ̀run.

23. Àwọn ìpín ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní Heburoni, láti gbé ìjọba Saulu lé Dafidi lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA nìyí:

24. Láti inú ẹ̀yà Juda, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó dín igba (6,800) wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀.

25. Láti inú ẹ̀yà Simeoni, ẹẹdẹgbaarin ó lé ọgọrun-un (7,100), àwọn akọni jagunjagun ni wọ́n wá.

26. Láti inú ẹ̀yà Lefi, wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó dín irinwo (4,600);

27. Jehoiada, olóyè, wá láti inú ìran Aaroni pẹlu ẹgbaaji ó dín ọọdunrun (3,700) ọmọ ogun

28. Sadoku ọdọmọkunrin akikanju jagunjagun wá, pẹlu ọ̀gágun mejilelogun ninu àwọn ará ilé baba rẹ̀.

29. Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà kan náà pẹlu Saulu, àwọn tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaaji (3,000). Tẹ́lẹ̀ rí, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ìdílé Saulu.

30. Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹrin (20,800) akikanju ati alágbára, tí wọ́n jẹ́ olókìkí ninu ìdílé wọn ni wọ́n wá.

Kronika Kinni 12