1. Àwọn ọkunrin wọnyi ni wọ́n lọ bá Dafidi ní Sikilagi, nígbà tí ó ń farapamọ́ fún Saulu, ọmọ Kiṣi; wọ́n wà lára àwọn akọni tí wọ́n ń ran Dafidi lọ́wọ́ lójú ogun.
2. Tafàtafà ni wọ́n, wọ́n sì lè fi ọwọ́ ọ̀tún ati ọwọ́ òsì ta ọfà tabi kí wọ́n fi fi kànnàkànnà. Ninu ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ti wá, wọ́n sì jẹ́ ìbátan Saulu.
3. Olórí wọn ni Ahieseri, lẹ́yìn náà, Joaṣi, ọmọ Ṣemaa; ará Gibea ni àwọn mejeeji. Lẹ́yìn wọn ni: Jesieli ati Peleti, àwọn ọmọ Asimafeti; Beraka, ati Jehu, ará Anatoti.