Kronika Kinni 11:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá parapọ̀, wọ́n wá sọ́dọ̀ Dafidi ní Heburoni, wọ́n ní, “Wò ó, ẹ̀jẹ̀ kan náà ni gbogbo wa pẹlu rẹ.

2. Látẹ̀yìnwá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni ò ń ṣáájú Israẹli lójú ogun. OLUWA Ọlọrun rẹ sì ti ṣèlérí fún ọ pé ìwọ ni o óo máa ṣe olùṣọ́ àwọn ọmọ Israẹli, eniyan òun, tí o óo sì jọba lé wọn lórí.”

Kronika Kinni 11