4. Wọ́n kó ọpọlọpọ eniyan jọ, wọ́n dí àwọn orísun omi ati àwọn odò tí ń ṣàn ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ní, “Kò yẹ kí ọba Asiria wá, kí ó bá omi tí ó tó báyìí.”
5. Ọba yan àwọn òṣìṣẹ́ láti mọ gbogbo àwọn odi tí ó wó lulẹ̀, ati láti kọ́ ilé ìṣọ́ sí orí wọn. Wọ́n tún mọ odi mìíràn yípo wọn. Ó tún Milo tí ó wà ní ìlú Dafidi ṣe kí ó fi lágbára síi, ó sì pèsè ọpọlọpọ nǹkan ìjà ati apata.
6. Ọba yan àwọn ọ̀gágun lórí àwọn eniyan, ó sì pe gbogbo wọn jọ sí gbàgede ẹnubodè ìlú. Ó dá wọn lọ́kàn le, ó ní,
7. “Ẹ múra, ẹ ṣọkàn gírí. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà níwájú ọba Asiria ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀; nítorí agbára ẹni tí ó wà pẹlu wa ju ti àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lọ.
8. Agbára ti ẹran ara ni àwọn ọmọ ogun tirẹ̀ ní, ṣugbọn OLUWA Ọlọrun ni ó wà pẹlu wa láti ràn wá lọ́wọ́ ati láti jà fún wa.” Ọ̀rọ̀ tí Hesekaya ọba Juda sọ sì fi àwọn eniyan rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀.