Kronika Keji 32:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan tí Hesekaya ṣe, tí ó sin OLUWA pẹlu òtítọ́, Senakeribu ọba Asiria wá gbógun ti Juda. Ó dó ti àwọn ìlú olódi wọn, ó lérò pé òun óo jagun gbà wọ́n.

2. Nígbà tí Hesekaya rí i pé Senakeribu ti pinnu láti gbógun ti Jerusalẹmu,

3. ó jíròrò pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bí wọn yóo ti ṣe dí ìṣàn omi tí ó wà lẹ́yìn odi ìlú; wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

4. Wọ́n kó ọpọlọpọ eniyan jọ, wọ́n dí àwọn orísun omi ati àwọn odò tí ń ṣàn ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ní, “Kò yẹ kí ọba Asiria wá, kí ó bá omi tí ó tó báyìí.”

5. Ọba yan àwọn òṣìṣẹ́ láti mọ gbogbo àwọn odi tí ó wó lulẹ̀, ati láti kọ́ ilé ìṣọ́ sí orí wọn. Wọ́n tún mọ odi mìíràn yípo wọn. Ó tún Milo tí ó wà ní ìlú Dafidi ṣe kí ó fi lágbára síi, ó sì pèsè ọpọlọpọ nǹkan ìjà ati apata.

6. Ọba yan àwọn ọ̀gágun lórí àwọn eniyan, ó sì pe gbogbo wọn jọ sí gbàgede ẹnubodè ìlú. Ó dá wọn lọ́kàn le, ó ní,

7. “Ẹ múra, ẹ ṣọkàn gírí. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà níwájú ọba Asiria ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀; nítorí agbára ẹni tí ó wà pẹlu wa ju ti àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lọ.

Kronika Keji 32