Kronika Keji 28:16-21 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ní àkókò yìí, Ahasi ranṣẹ lọ bẹ ọba Asiria lọ́wẹ̀,

17. nítorí pé àwọn ará Edomu tún pada wá gbógun ti Juda; wọ́n ṣẹgun wọn, wọ́n sì kó àwọn kan ninu wọn lẹ́rú lọ.

18. Àwọn ará Filistia ti gbógun ti àwọn ìlú tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati ní agbègbè Nẹgẹbu, ní Juda. Wọ́n jagun gba Beti Ṣemeṣi, Aijaloni, ati Gederotu, wọ́n sì gba Soko, Timna, ati Gimso pẹlu àwọn ìletò ìgbèríko wọn, wọ́n bá ń gbé ibẹ̀.

19. OLUWA rẹ Juda sílẹ̀ nítorí Ahasi, ọba Juda, nítorí pé ó hùwà ìríra ní Juda, ó sì ṣe aiṣootọ sí OLUWA.

20. Nítorí náà Tigilati Pileseri, ọba Asiria gbógun ti Ahasi, ó sì fìyà jẹ ẹ́, dípò kí ó ràn án lọ́wọ́.

21. Ahasi kó ohun ìṣúra inú ilé OLUWA, ati ti ààfin, ati ti inú ilé àwọn ìjòyè, ó fi san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Asiria, sibẹsibẹ ọba Asiria kò ràn án lọ́wọ́.

Kronika Keji 28