25. Ọba fara gbọgbẹ́ ninu ogun náà, nígbà tí àwọn ogun Siria sì lọ tán, àwọn balogun rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn nítorí pé ó pa ọmọ Jehoiada alufaa, wọ́n sì pa á lórí ibùsùn rẹ̀. Wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, ṣugbọn kì í ṣe inú ibojì àwọn ọba.
26. Àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba ni Sabadi, ọmọ Ṣimeati ará Amoni, ati Jehosabadi ọmọ Ṣimiriti ará Moabu.
27. Ìtàn àwọn ọmọ rẹ̀, ati ọpọlọpọ àsọtẹ́lẹ̀ tí a sọ nípa rẹ̀, ati bí ó ti tún ilé Ọlọrun ṣe wà, tí a kọ ọ́ sinu ìwé Ìtàn Àwọn Ọba. Amasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.