5. Jehoṣafati bá dìde dúró láàrin àwọn tí wọ́n ti Juda ati Jerusalẹmu wá sinu tẹmpili, níbi tí wọ́n péjọ sí níwájú gbọ̀ngàn tuntun,
6. ó ní, “OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa, ṣebí ìwọ ni Ọlọrun ọ̀run. Ìwọ ni o ni àkóso ìjọba gbogbo orílẹ̀-èdè. Agbára ati ipá wà ní ìkáwọ́ rẹ, kò sì sí ẹni tí ó tó dojú kọ ọ́.
7. Ṣebí ìwọ, Ọlọrun wa, ni o lé gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ kúrò fún àwa ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, tí o sì fi ilẹ̀ náà fún arọmọdọmọ Abrahamu, ọ̀rẹ́ rẹ, títí lae?
8. Wọ́n ti ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì ti kọ́ ibi mímọ́ sibẹ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ,
9. nítorí pé tí ibi bá dé bá wa, tabi ìdájọ́, tabi àjàkálẹ̀ àrùn, tabi ìyàn, a óo dúró níwájú ilé yìí ati níwájú rẹ, nítorí orúkọ rẹ wà ninu ilé yìí. A óo ké pè ọ́ ninu ìyọnu wa, o óo gbọ́ tiwa, o óo sì gbà wá.
10. “Nisinsinyii, wo àwọn ọmọ ogun Amoni, ati ti Moabu ati ti Òkè Seiri, àwọn tí o kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli bá jà nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti, o kò jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n run.
11. Wò ó! Wọ́n ń fi burúkú san ire fún wa, wọ́n ń bọ̀ wá lé wa kúrò lórí ilẹ̀ rẹ, tí o fún wa bí ìní.
12. Ọlọrun wa, dá wọn lẹ́jọ́. Nítorí pé agbára wa kò tó láti dojú kọ ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun wọn tí wọn ń kó bọ̀ wá bá wa jà. A kò mọ ohun tí a lè ṣe, ìwọ ni a gbójú sókè tí à ń wò.”
13. Gbogbo àwọn ọkunrin Juda dúró níwájú OLUWA pẹlu àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn.