Kronika Keji 17:17-19 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Àwọn olórí ogun láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini ni: Eliada, akọni ọmọ ogun, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn ọmọ ogun tí wọn ń lo apata ati ọrun ni wọ́n wà lábẹ́ rẹ̀.

18. Igbákejì ni Jehosabadi; òun náà ní ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) ọmọ ogun tí wọ́n ti dira ogun, lábẹ́ rẹ̀.

19. Gbogbo àwọn wọnyi ni wọ́n wà lábẹ́ ọba ní Jerusalẹmu, láìka àwọn tí ó fi sí àwọn ìlú olódi ní gbogbo ilẹ̀ Juda.

Kronika Keji 17