Kronika Keji 17:11-16 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Àwọn kan ninu àwọn ará Filistia mú ẹ̀bùn ati fadaka wá fún Jehoṣafati gẹ́gẹ́ bíi ìṣákọ́lẹ̀. Àwọn ará Arabia náà sì mú ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) àgbò, ati ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) òbúkọ wá.

12. Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i, ó kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ ati àwọn ìlú tí wọn ń kó ìṣúra pamọ́ sí ní Juda;

13. ó ní ilé tí wọn ń kó nǹkan pamọ́ sí ní àwọn ìlú ńláńlá Juda.Ó sì ní àwọn akọni ọmọ ogun ní Jerusalẹmu.

14. Iye àwọn ọmọ ogun tí ó kó jọ nìyí gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: Adinai ni olórí ogun ẹ̀yà Juda, ó sì ní ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọmọ ogun lábẹ́ rẹ̀.

15. Olórí ogun tí ó pọwọ́ lé e ni Jehohanani, ó ní ọ̀kẹ́ mẹrinla (280,000) ọmọ ogun lábẹ́ rẹ̀.

16. Olórí ogun kẹta ni Amasaya, ọmọ Sikiri, ẹni tí ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ OLUWA, ó ní ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) akọni ọmọ ogun.

Kronika Keji 17