Kronika Keji 15:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Asaraya ọmọ Odedi.

2. Ó lọ pàdé Asa, ó wí fún un pé, “Gbọ́ mi, ìwọ Asa, ati gbogbo ẹ̀yin ọmọ Juda ati ti Bẹnjamini, OLUWA wà pẹlu yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin náà bá wà pẹlu rẹ̀. Bí ẹ bá wá a, ẹ óo rí i. Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun náà yóo kọ̀ yín sílẹ̀.

3. Ọjọ́ pẹ́, tí Israẹli ti wà láìní Ọlọrun òtítọ́, wọn kò ní alufaa tí ń kọ́ ni, wọn kò sì ní òfin.

4. Ṣugbọn nígbà tí ìyọnu dé, wọ́n yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Wọ́n wá OLUWA, wọ́n sì rí i.

Kronika Keji 15