1. Láìpẹ́, lẹ́yìn tí Rehoboamu fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ tí ó di alágbára, òun ati àwọn eniyan rẹ̀ kọ òfin OLUWA sílẹ̀.
2. Nígbà tí ó di ọdún karun-un ìjọba rẹ̀, Ọlọrun fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí aiṣootọ rẹ̀. Ṣiṣaki ọba Ijipti gbógun ti Jerusalẹmu pẹlu ẹgbẹfa (1,200) kẹ̀kẹ́ ogun,