Kronika Keji 11:16-19 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ sin Ọlọrun Israẹli tọkàntọkàn láti inú olukuluku ẹ̀yà Israẹli, tẹ̀lé àwọn alufaa wá sí Jerusalẹmu láti ṣe ìrúbọ sí OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.

17. Wọ́n sọ ìjọba Juda di alágbára, wọ́n sì ṣe alátìlẹ́yìn fún Rehoboamu ọmọ Solomoni fún ọdún mẹta; wọ́n ń rìn ní ìlànà Dafidi ati ti Solomoni ní gbogbo ìgbà náà.

18. Rehoboamu fẹ́ Mahalati, ọmọ Jerimotu, ọmọ Dafidi, ìyá rẹ̀ ni Abihaili, ọmọ Eliabu, ọmọ Jese.

19. Iyawo Rehoboamu yìí bí ọmọkunrin mẹta fún un; wọ́n ń jẹ́: Jeuṣi, Ṣemaraya ati Sahamu.

Kronika Keji 11