14. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni Oluwa pàṣẹ pé kí àwọn tí ó ń waasu ìyìn rere máa jẹ láti inú iṣẹ́ ìyìn rere.
15. Ṣugbọn n kò lo anfaani yìí rí. Kì í ṣe pé kí n lè lo anfaani yìí ni mo ṣe ń sọ ohun tí mò ń sọ yìí. Nítorí ó yá mi lára kí ń kúkú kú jù pé kí ẹnikẹ́ni wá sọ ọ̀nà ìṣògo mi di asán lọ.
16. Nítorí bí mo bá ń waasu ìyìn rere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa fi ṣògo. Nítorí dandan ni ó jẹ́ fún mi. Bí n kò bá waasu ìyìn rere, mo gbé!
17. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé èmi fúnra mi ni mo yàn láti máa ṣe iṣẹ́ yìí, mo ní ẹ̀tọ́ láti retí èrè níbẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ dandan ni mo fi ń ṣe é, iṣẹ́ ìríjú tí a fi sí ìtọ́jú mi ni.
18. Kí wá ni èrè mi? Mo ní ìtẹ́lọ́rùn pé mò ń waasu ìyìn rere lọ́fẹ̀ẹ́, n kò lo anfaani tí ó tọ́ sí mi ninu iṣẹ́ ìyìn rere.
19. Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òmìnira ni mo wà, tí n kò sì sí lábẹ́ ẹnìkan, sibẹ mo sọ ara mi di ẹrú gbogbo eniyan kí n lè mú ọpọlọpọ wọn wá sọ́dọ̀ Jesu.