Kọrinti Kinni 10:23-29 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Lóòótọ́, “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe,” bí àwọn kan ti ń wí. Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan ni ó ń ṣe eniyan ní anfaani. “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe.” Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí a lè ṣe ni ó ń mú ìdàgbà wá.

24. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe máa wá ire ti ara rẹ̀ bíkòṣe ire ẹnìkejì rẹ̀.

25. Kí ẹ jẹ ohunkohun tí ẹ bá rà ní ọjà láì wádìí ohunkohun kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́;

26. “Nítorí Oluwa ni ó ni ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.”

27. Bí ẹnìkan ninu àwọn alaigbagbọ bá pè yín wá jẹun, tí ẹ bá gbà láti lọ, ẹ jẹ ohunkohun tí ó bá gbé kalẹ̀ níwájú yín láì wádìí ohunkohun, kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́.

28. Ṣugbọn bí ẹnìkan bá sọ fun yín pé, “A ti fi oúnjẹ yìí ṣe ìrúbọ,” ẹ má jẹ ẹ́, nítorí ẹni tí ó sọ bẹ́ẹ̀ ati nítorí ẹ̀rí-ọkàn.

29. Kì í ṣe ẹ̀rí-ọkàn tiyín ni mò ń sọ bíkòṣe ẹ̀rí-ọkàn ti ẹni tí ó pe akiyesi yín sí oúnjẹ náà.Kí ló dé tí yóo fi jẹ́ pé ẹ̀rí-ọkàn ẹlòmíràn ni yóo máa sọ bí n óo ti ṣe lo òmìníra mi?

Kọrinti Kinni 10