Kọrinti Keji 8:6-19 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ìdí nìyí tí a fi gba Titu níyànjú pé, nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí láàrin yín, kí ó kúkú ṣe é parí.

7. Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ní, tí ẹ sì ní lọpọlọpọ: igbagbọ, ọ̀rọ̀ sísọ, ìmọ̀, ati ìtara ní ọ̀nà gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tí ẹ ní sí wa. A fẹ́ kí ìtara yín túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìfẹ́ pẹlu.

8. N kò pa èyí láṣẹ. Mo fi àpẹẹrẹ ìtara àwọn ẹlòmíràn siwaju yín láti fi dán yín wò ni, bóyá ẹ ní ìfẹ́ tòótọ́ tabi ẹ kò ní.

9. Nítorí ẹ mọ oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi, pé nítorí tiwa, òun tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ di aláìní, kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípa àìní tirẹ̀.

10. Èrò mi lórí ọ̀rọ̀ yìí ni pé ohun tí ó dára jùlọ fun yín ni. Nígbà tí kì í tíí ṣe pé ẹ ti ń ṣe é nìkan ni, ṣugbọn tìfẹ́tìfẹ́ ni ẹ ti fi ń ṣe é láti ọdún tí ó kọjá,

11. ó tó àkókò wàyí, ẹ ṣe é parí. Irú ìtara tí ẹ fẹ́ fi ṣe é ni kí ẹ fi parí rẹ̀. Kí ẹ ṣe é gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ní tó.

12. Bí ìfẹ́ láti mú ọrẹ wá bá wà, Ọlọrun gba ohun tí eniyan bá mú wá. Ọlọrun kò bèèrè ohun tí eniyan kò ní.

15. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Ẹni tí ó kó ọ̀pọ̀ kò ní jù, ẹni tí ó kó díẹ̀ kò ṣe aláìní tó.”

16. Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fi irú ìtara kan náà tí mo ní sí ọkàn Titu.

17. Nítorí nígbà tí a sọ pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín, pẹlu ayọ̀ ni ó fi gbà láti wá. Òun fúnrarẹ̀ tilẹ̀ ní àníyàn láti wá sọ́dọ̀ yín tẹ́lẹ̀.

18. A rán arakunrin tí ó lókìkí ninu gbogbo àwọn ìjọ nítorí iṣẹ́ rẹ̀ nípa ìyìn rere pé kí ó bá a wá.

19. Kì í ṣe pé ó lókìkí nìkan ni, ṣugbọn òun ni ẹni tí gbogbo àwọn ìjọ yàn pé kí ó máa bá wa kiri nípa iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ tí à ń ṣe fún ògo Oluwa ati láti fi ìtara wa hàn.

Kọrinti Keji 8