Kọrinti Keji 7:14-16 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nítorí bí mo bá ti sọ ohunkohun nípa yín, tí mo sì ti fi ọwọ́ yín sọ̀yà, ẹ kò dójú tì mí. Ṣugbọn bí ó ti jẹ́ pé òtítọ́ ni gbogbo nǹkan tí a ti sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ náà ni ọwọ́ yín tí a fi sọ̀yà fún Titu jẹ́ òtítọ́.

15. Inú Titu dùn si yín lọpọlọpọ nígbà tí ó ranti bí gbogbo yín ti múra láti ṣe ohun tí ó sọ fun yín ati bí ẹ ti gbà á pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì.

16. Mo láyọ̀ pé mo lè gbẹ́kẹ̀lé yín ninu ohun gbogbo.

Kọrinti Keji 7