Kọrinti Keji 5:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí a mọ̀ pé bí àgọ́ ara tí a fi ṣe ilé ní ayé yìí bá wó, a ní ilé kan lọ́dọ̀ Ọlọrun, tí a kò fi ọwọ́ kọ́, tí yóo wà lọ́run títí laelae.

2. Nítorí ninu àgọ́ ara yìí à ń kérora, à ń tiraka láti gbé ilé wa ti ọ̀run wọ̀.

3. A ní ìrètí pé bí a bá gbé e wọ̀, a kò ní bá ara wa níhòòhò.

Kọrinti Keji 5