Kọrinti Keji 1:8-14 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ẹ̀yin ará, a kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa ìpọ́njú tí ó tayọ agbára wa tí a ní ní Esia, Ìdààmú náà wọ̀ wá lọ́rùn tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí wa fi fẹ́rẹ̀ bọ́.

9. A ṣe bí wọ́n tí dá wa lẹ́bi ikú ni. Kí á má baà gbẹ́kẹ̀lé ara wa, bíkòṣe Ọlọrun, ni ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Nítorí Ọlọrun níí jí òkú dìde.

10. Ọlọrun ni ó yọ wá ninu ewu ńlá náà, òun ni yóo sì máa yọ wá. Òun ni a ní ìrètí ninu rẹ̀; yóo sì tún máa yọ wá,

11. bí ẹ bá ń fi adura yín ràn wá lọ́wọ́. Nígbà náà ni ọpọlọpọ eniyan yóo ṣọpẹ́ nítorí ọpọlọpọ oore tí Ọlọrun ṣe fún wa.

12. Nǹkankan wà tí a lè fi ṣe ìgbéraga, ẹ̀rí-ọkàn wa sì jẹ́rìí sí i pé pẹlu ọkàn kan ati inú kan níwájú Ọlọrun ni a fi ń bá gbogbo eniyan lò, pàápàá jùlọ ẹ̀yin gan-an. Kì í ṣe ọgbọ́n eniyan bíkòṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.

13. Kò sí ohunkohun tí a kọ si yín tí ẹ kò lè kà kí ó ye yín. Mo sì ní ìrètí pé yóo ye yín jálẹ̀.

14. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ẹ kò ì tíì mọ̀ wá dáradára, ẹ óo rí i pé a óo jẹ́ ohun ìṣògo fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà yóo ti jẹ́ fún wa ní ọjọ́ tí Oluwa wa, Jesu, bá dé.

Kọrinti Keji 1