Kolose 4:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ọ̀gá, ohun tí ó dára ati ohun tí ó yẹ ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Kí ẹ ranti pé ẹ̀yin náà ní Ọ̀gá kan ní ọ̀run.

2. Ẹ tẹra mọ́ adura gbígbà. Ẹ máa fi ọkàn bá adura yín lọ. Kí ẹ sì máa dúpẹ́.

3. Ẹ tún máa gbadura fún wa, pé kí Ọlọrun lè ṣí ìlẹ̀kùn iwaasu fún wa, kí á lè sọ ìjìnlẹ̀ àṣírí Kristi. Nítorí èyí ni mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n.

4. Kí ẹ gbadura pé kí n lè ṣe àlàyé bí ó ti yẹ.

5. Ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín pẹlu ọgbọ́n níwájú àwọn alaigbagbọ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àkókò kan kọjá láìjẹ́ pé ẹ lò ó bí ó ti yẹ.

Kolose 4