34. Lẹ́yìn náà Joṣua ka gbogbo òfin náà sókè ati ibukun tí ó wà ninu rẹ̀, ati ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin.
35. Kò sí ohun tí Mose pa láṣẹ tí Joṣua kò kà sí etígbọ̀ọ́ gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli, ati ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati àlejò tí wọ́n wà ní ààrin wọn.