Joṣua 24:20-28 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Lẹ́yìn tí OLUWA bá ti ṣe yín lóore, bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn oriṣa àjèjì, yóo yipada láti ṣe yín níbi, yóo sì pa yín run.”

21. Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “Rárá o, OLUWA ni a óo máa sìn.”

22. Joṣua bá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín, pé OLUWA ni ẹ yàn láti máa sìn.”Wọ́n dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí.”

23. Lẹ́yìn náà, Joṣua sọ fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ kó àwọn oriṣa àjèjì tí ó wà láàrin yín dànù, kí ẹ sì fi ọkàn sọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli.”

24. Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “OLUWA Ọlọrun wa ni a óo máa sìn, tirẹ̀ ni a óo sì máa gbọ́.”

25. Joṣua bá dá majẹmu pẹlu àwọn eniyan náà ní ọjọ́ náà, ó sì ṣe òfin ati ìlànà fún wọn ní Ṣekemu.

26. Ó kọ ọ̀rọ̀ náà sinu ìwé òfin Ọlọrun, ó gbé òkúta ńlá kan, ó sì fi gúnlẹ̀ lábẹ́ igi Oaku, ní ibi mímọ́ OLUWA,

27. ó bá wí fún gbogbo wọn pé, “Ẹ wo òkúta yìí, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin wa, nítorí pé ó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ fún wa, nítorí náà, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín, kí ẹ má baà hùwà aiṣododo sí Ọlọrun yín.”

28. Joṣua bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà máa lọ, kí olukuluku pada sí orí ilẹ̀ rẹ̀.

Joṣua 24