20. Láti inú ilẹ̀ ẹ̀yà Efuraimu ni wọ́n ti gba ìlú fún àwọn ọmọ Kohati yòókù, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Lefi.
21. Àwọn ni wọ́n fún ní ìlú Ṣekemu, tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, ati àwọn pápá ìdaran rẹ̀ tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu. Wọ́n tún fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi, pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Geseri,
22. Kibusaimu ati Beti Horoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.
23. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Dani, wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Eliteke, Gibetoni.
24. Aijaloni ati Gati Rimoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.
25. Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase, wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Taanaki, ati Gati Rimoni, wọ́n jẹ́ ìlú meji.
26. Ìlú àwọn ọmọ Kohati yòókù jẹ́ mẹ́wàá pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn.
27. Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase ni wọ́n ti fún àwọn ọmọ Geriṣoni ninu ìdílé Lefi ní àwọn ìlú wọnyi: Golani ní ilẹ̀ Baṣani pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Golani yìí jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, ati Beeṣitera pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n jẹ́ ìlú meji.