5. Bí ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bá ń lé e bọ̀, wọn kò ní fi lé e lọ́wọ́, nítorí pé ó ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀ ni, kò sì ní ìkùnsínú sí i tẹ́lẹ̀.
6. Ìlú yìí ni yóo máa gbé títí tí àwọn ìgbìmọ̀ yóo fi ṣe ìdájọ́ rẹ̀, yóo máa gbé ibẹ̀ títí tí ẹni tí ó jẹ́ olórí alufaa ní àkókò náà yóo fi kú, lẹ́yìn náà ẹni tí ó ṣèèṣì pa eniyan yìí lè pada lọ sí ilé rẹ̀ ati sí ìlú rẹ̀ níbi tí ó ti sá wá.”
7. Wọ́n ya Kedeṣi sọ́tọ̀ ní Galili ní agbègbè olókè ti Nafutali, ati Ṣekemu ní agbègbè olókè ti Efuraimu, ati Kiriati Ariba (tí wọ́n ń pè ní Heburoni), ní agbègbè olókè ti Juda.
8. Ní òdìkejì odò Jọdani, ní apá ìlà oòrùn Jẹriko, wọ́n ya Beseri tí ó wà ninu aṣálẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú sọ́tọ̀. Wọ́n ya Ramoti tí ó wà ní Gileadi sọ́tọ̀ ní agbègbè ti ẹ̀yà Gadi, ati Golani tí ó wà ní Baṣani, ní agbègbè ti ẹ̀yà Manase.