Jona 3:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA tún bá Jona sọ̀rọ̀ nígbà keji, ó ní:

2. “Dìde, lọ sí Ninefe, ìlú ńlá nì, kí o sì kéde iṣẹ́ tí mo rán ọ fún gbogbo eniyan ibẹ̀.”

3. Jona bá dìde, ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA. Ninefe jẹ́ ìlú tí ó tóbi, ó gbà tó ìrìn ọjọ́ mẹta láti la ìlú náà já.

4. Jona rin ìlú náà fún odidi ọjọ́ kan, ó sì ń kéde pé: “Níwọ̀n ogoji ọjọ́ sí i, Ninefe óo parun.”

5. Àwọn ará Ninefe gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbọ́, wọ́n bá kéde pé kí gbogbo eniyan gbààwẹ̀, àtọmọdé, àtàgbà, wọ́n sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.

Jona 3