Johanu 7:34-42 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Ẹ óo wá mi, ẹ kò ní rí mi, ibi tí mo bá wà, ẹ kò ní lè dé ibẹ̀.”

35. Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Níbo ni ọkunrin yìí yóo lọ tí àwa kò fi ní rí i? Àbí ó ha fẹ́ lọ sí ààrin àwọn ará wa tí ó fọ́nká sí ààrin àwọn Giriki ni?

36. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí tí ó sọ pé, ‘Ẹ óo wá mi, ẹ kò ní rí mi, níbi tí mo bá wà, ẹ kò ní lè dé ibẹ̀?’ ”

37. Nígbà tí ó di ọjọ́ tíí àjọ̀dún yóo parí, tíí ṣe ọjọ́ tí ó ṣe pataki jùlọ, Jesu dìde dúró, ó kígbe pé, “Bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó wá sọ́dọ̀ mi kí ó mu omi.

38. Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóo ti máa sun jáde, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.”

39. Ó wí èyí nípa Ẹ̀mí tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ yóo gbà láì pẹ́, nítorí nígbà náà ẹnikẹ́ni kò ì tíì rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí gbà nítorí a kò ì tíì ṣe Jesu lógo.

40. Ninu àwọn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, àwọn kan ń sọ pé, “Òun ni wolii tí à ń retí nítòótọ́.”

41. Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Òun ni Mesaya.”Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Báwo ni Mesaya ti ṣe lè wá láti Galili?

42. Ṣebí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé láti inú ìdílé Dafidi, ní Bẹtilẹhẹmu ìlú Dafidi, ni Mesaya yóo ti wá?”

Johanu 7