Johanu 6:11-23 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Jesu wá mú burẹdi náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá pín in fún àwọn eniyan tí ó jókòó. Bákan náà ni ó ṣe sí ẹja, ó fún olukuluku bí ó ti ń fẹ́.

12. Lẹ́yìn tí àwọn eniyan ti jẹ ẹja ní àjẹtẹ́rùn, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó oúnjẹ tí ó kù jọ, kí ohunkohun má baà ṣòfò.”

13. Wọ́n bá kó o jọ. Àjẹkù burẹdi marun-un náà kún agbọ̀n mejila, lẹ́yìn tí àwọn eniyan ti jẹ tán.

14. Nígbà tí àwọn eniyan rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, wọ́n ní, “Dájúdájú, eléyìí ni wolii Ọlọrun náà tí ó ń bọ̀ wá sí ayé.”

15. Nígbà tí Jesu mọ̀ pé wọn ń fẹ́ wá fi ipá mú òun kí wọ́n sì fi òun jọba, ó yẹra kúrò níbẹ̀, òun nìkan tún pada lọ sórí òkè.

16. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí èbúté,

17. wọ́n wọ ọkọ̀, wọ́n ń lọ sí Kapanaumu ní òdìkejì òkun. Òkùnkùn ti ṣú ṣugbọn Jesu kò ì tíì dé ọ̀dọ̀ wọn.

18. Ni omi òkun bá bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nítorí afẹ́fẹ́ líle ń fẹ́.

19. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wa ọkọ̀ bí ibùsọ̀ mẹta tabi mẹrin wọ́n rí Jesu, ó ń rìn lórí òkun, ó ti súnmọ́ etí ọkọ̀ wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n.

20. Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.”

21. Wọ́n bá fi tayọ̀tayọ̀ gbà á sinu ọkọ̀. Lẹsẹkẹsẹ ọkọ̀ sì gúnlẹ̀ sí ibi tí wọn ń lọ.

22. Ní ọjọ́ keji, àwọn tí wọ́n dúró ní òdìkejì òkun rí i pé ọkọ̀ kanṣoṣo ni ó wà níbẹ̀. Wọ́n tún wòye pé Jesu kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni wọ́n lọ.

23. Ṣugbọn àwọn ọkọ̀ mìíràn wá láti Tiberiasi lẹ́bàá ibi tí àwọn eniyan ti jẹun lẹ́yìn tí Oluwa ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun.

Johanu 6