12. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ yóo ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; yóo tilẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó ju ìwọ̀nyí lọ, nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba.
13. Èmi yóo ṣe ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi, kí ògo Baba lè yọ lára Ọmọ.
14. Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ mi ní orúkọ mi, èmi yóo ṣe é.
15. “Bí ẹ bá fẹ́ràn mi, ẹ óo pa òfin mi mọ́.
16. N óo bèèrè lọ́wọ́ Baba, yóo wá fun yín ní Alátìlẹ́yìn mìíràn tí yóo wà pẹlu yín títí lae.
17. Òun ni Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn. Ayé kò lè gbà á nítorí ayé kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, nítorí ó ń ba yín gbé, ó sì wà ninu yín.