27. Jesu bá tún sọ pé, “Ọkàn mí dàrú nisinsinyii. Kí ni ǹ bá wí? Ọkàn kan ń sọ pé kí n wí pé, ‘Baba, yọ mí kúrò ninu àkókò yìí.’ Ṣugbọn nítorí àkókò yìí gan-an ni mo ṣe wá sí ayé.
28. Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.”Ohùn kan bá wá láti ọ̀run, ó ní, “Mo ti ṣe é lógo ná, èmi óo sì tún ṣe é lógo sí i.”
29. Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan tí wọ́n dúró, tí wọ́n gbọ́, ń sọ pé, “Ààrá sán!” Àwọn ẹlòmíràn ń sọ pé, “Angẹli ló bá a sọ̀rọ̀.”
30. Jesu wí fún wọn pé, “Ohùn yìí kò wá nítorí tèmi bí kò ṣe nítorí tiyín.
31. Àkókò tó fún ìdájọ́ ayé yìí. Nisinsinyii ni a óo lé aláṣẹ ayé yìí jáde.