Johanu 1:46-48 BIBELI MIMỌ (BM)

46. Nataniẹli bi í pé, “Ṣé nǹkan rere kan lè ti Nasarẹti wá?”Filipi dá a lóhùn pé, “Wá wò ó.”

47. Jesu rí Nataniẹli bí ó ti ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ nípa rẹ̀ pé, “Wo ọmọlúwàbí, ọmọ Israẹli tí kò ní ẹ̀tàn ninu.”

48. Nataniẹli bi í pé, “Níbo ni o ti mọ̀ mí?”Jesu dá a lóhùn pé, “Kí Filipi tó pè ọ́, nígbà tí o wà ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, mo ti rí ọ.”

Johanu 1