Johanu Kẹta 1:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Èmi, Alàgbà, ni mo kọ ìwé yìí sí ọ, Gaiyu olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ràn nítòótọ́.

2. Olùfẹ́, mo gbadura pé kí ó dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà ati pé kí o ní ìlera, gẹ́gẹ́ bí o ti ní ìlera ninu ẹ̀mí.

3. Inú mi dùn nígbà tí àwọn arakunrin dé, tí wọ́n ròyìn rẹ pé o ṣe olóòótọ́ sí ọ̀nà òtítọ́, ati pé ò ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́.

4. Ayọ̀ mi kì í lópin, nígbà tí mo bá gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́.

Johanu Kẹta 1