3. Oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi Ọmọ Baba yóo wà pẹlu wa ninu òtítọ́ ati ìfẹ́.
4. Mo láyọ̀ pupọ nítorí mo ti rí àwọn tí wọn ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́ ninu àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí a ti gba òfin lọ́dọ̀ Baba.
5. Nisinsinyii mo bẹ̀ ọ́, arabinrin, kì í ṣe pé mò ń kọ òfin titun sí ọ, yàtọ̀ sí èyí tí a ti níláti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ọmọnikeji wa.
6. Èyí ni ìfẹ́, pé kí á máa gbé ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin Ọlọrun. Bí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, òfin yìí ni pé kí ẹ máa rìn ninu ìfẹ́.
7. Ọpọlọpọ àwọn ẹlẹ́tàn ti dé inú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá ninu ara eniyan. Àwọn yìí ni ẹlẹ́tàn ati alátakò Kristi.
8. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa iṣẹ́ tí ẹ ti ṣe run, kí ẹ lè gba èrè kíkún.