Bí mo bá sùn lóru,n óo máa ronú pé,‘Ìgbà wo ni ilẹ̀ óo mọ́ tí n óo dìde?’Òru a gùn bí ẹni pé ojúmọ́ kò ní mọ́ mọ́,ma wá máa yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún,títí ilẹ̀ yóo fi mọ́.