Jobu 42:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jobu bá dá OLUWA lóhùn ó ní:

2. “Mo mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo,kò sì sí ohun tí ó lè da ìpinnu rẹ rú.

3. Ta nìyí tí ń fi ìmọ̀ràn pamọ́ láìní òye?Àwọn ohun tí mo sọ kò yé mi,ìyanu ńlá ni wọ́n jẹ́ fún mi,n kò sì mọ̀ wọ́n.

4. O ní kí n tẹ́tí sílẹ̀,nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀,kí n sì dáhùn nígbà tí o bá bèèrè nǹkan lọ́wọ́ mi.

5. Ìró rẹ ni mo gbọ́ tẹ́lẹ̀,ṣugbọn nisinsinyii mo ti rí ọ;

6. nítorí náà, ojú ara mi tì mí,fún ohun tí mo ti sọ,mo sì ronupiwada ninu erùpẹ̀ ati eérú.”

7. Lẹ́yìn ìgbà tí OLUWA ti bá Jobu sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Elifasi ará Temani pé, “Inú ń bí mi sí ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ mejeeji. Nítorí ẹ kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi, bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.

8. Nítorí náà, mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje lọ sí ọ̀dọ̀ Jobu kí o rú ẹbọ sísun fún ara rẹ; Jobu iranṣẹ mi yóo sì gbadura fún ọ, n óo gbọ́ adura rẹ̀, n kò sì ní ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ. Nítorí o kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi gẹ́gẹ́ bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.”

Jobu 42