Jobu 41:30-34 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Ìpẹ́ ikùn rẹ̀ dàbí àpáàdì tí ó mú,wọn ń fa ilẹ̀ tútù ya bí ọkọ́.

31. Ó mú kí ibú hó bí omi inú ìkòkò,ó ṣe òkun bí ìkòkò òróró ìpara.

32. Bí ó bá ń rìn lọ, ipa ọ̀nà rẹ̀ a máa hàn lẹ́yìn rẹ̀,eniyan á rò pé òkun ń hó bí ọṣẹ ni.

33. Kò sí ohun tí a lè fi wé láyé,ẹ̀dá tí ẹ̀rù kì í bà.

34. Ó fojú tẹmbẹlu gbogbo ohun gíga,ó sì jọba lórí gbogbo àwọn ọmọ agbéraga.”

Jobu 41