Jobu 38:12-21 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Jobu, láti ọjọ́ tí o ti dé ayé,ǹjẹ́ o ti pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mọ́ rí,tabi pé kí àfẹ̀mọ́jú mọ́ àkókò rẹ̀,

13. kí ìmọ́lẹ̀ lè tàn sí gbogbo ayé,kí ó sì lè gbọn àwọn ẹni ibi dànù,kúrò ní ibi ìsápamọ́sí wọn?

14. A ti yí ayé pada bí amọ̀ tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀,ati bí aṣọ tí a pa láró.

15. A mú ìmọ́lẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹni ibi,a sì ká wọn lápá kò.

16. “Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí,tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí?

17. Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí,tabi o ti rí ìlẹ̀kùn òkùnkùn biribiri rí?

18. Ṣé o mọ̀ bí ayé ti tóbi tó?Dá mi lóhùn, bí o bá mọ àwọn nǹkan wọnyi.

19. “Níbo ni ọ̀nà ilé ìmọ́lẹ̀,ibo sì ni ibùgbé òkùnkùn,

20. tí o óo fi lè mú un lọ sí ààyè rẹ̀,tí o fi lè mọ ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀?

21. Dájúdájú o mọ̀, nítorí pé wọ́n ti bí ọ nígbà náà,o sá ti dàgbà!

Jobu 38