Jobu 35:12-16 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Wọ́n kígbe níbẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lóhùn,nítorí ìgbéraga àwọn eniyan burúkú.

13. Dájúdájú Ọlọrun kì í gbọ́ igbe asán,Olodumare kò tilẹ̀ náání rẹ̀.

14. Kí á má tilẹ̀ sọ ti ìwọ Jobu, tí o sọ péo kò rí i,ati pé ẹjọ́ rẹ wà níwájú rẹ̀,o sì ń dúró dè é!

15. Ṣugbọn nisinsinyii, nítorí pé inú kì í bí i kí ó jẹ eniyan níyà,bẹ́ẹ̀ ni kò ka ẹ̀ṣẹ̀ kún lọ títí.

16. Jobu kàn ń la ẹnu,ó sì ń sọ̀rọ̀ lásán ni.Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pọ̀, ṣugbọn kò mú ọgbọ́n lọ́wọ́.”

Jobu 35