14. Bí Ọlọrun bá gba ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,tí ó sì gba èémí rẹ̀ pada sọ́dọ̀,
15. gbogbo eniyan ni yóo ṣègbé,tí wọn yóo sì pada di erùpẹ̀.
16. “Bí ẹ bá ní òye, ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ.
17. Ǹjẹ́ ẹni tí ó kórìíra ìdájọ́ ẹ̀tọ́ lè jẹ́ olórí?Àbí ẹ lè dá olódodo ati alágbára lẹ́bi?
18. Ẹni tí ó tó pe ọba ní eniyan lásán,tí ó tó pe ìjòyè ní ẹni ibi;
19. ẹni tí kì í ṣe ojuṣaaju fún àwọn ìjòyè,tí kì í sì í ka ọlọ́rọ̀ sí ju talaka lọ,nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn.
20. Wọn á kú ikú òjijì, ní ọ̀gànjọ́ òru;á mi gbogbo eniyan jìgìjìgì, wọn a sì kú.Ikú á mú àwọn alágbára lọ láì jẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn wọ́n.
21. Nítorí pé ojú rẹ̀ tó gbogbo ọ̀nà tí eniyan ń tọ̀,ó sì rí gbogbo ìrìn ẹsẹ̀ wọn.
22. Kò sí ibi òkùnkùn biribiri kankan,tí àwọn eniyan burúkú lè fi ara pamọ́ sí.