Jobu 33:20-26 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu rẹ̀ yóo kọ oúnjẹ,oúnjẹ àdídùn óo sì rùn sí i.

21. Eniyan á rù hangangan,wọn a sì fẹ́rẹ̀ lè máa ka egungun rẹ̀.

22. Ọkàn rẹ̀ á súnmọ́ ibojì,ẹ̀mí rẹ̀ a sì súnmọ́ àwọn iranṣẹ ikú.

23. Bí angẹli kan bá wà pẹlu rẹ̀,tí ó wà fún un bí onídùúró,àní, ọ̀kan láàrin ẹgbẹrun,tí yóo sọ ohun tí ó tọ́ fún un,

24. tí yóo ṣàánú rẹ̀, tí yóo sì wí pé,‘Ẹ gbà á sílẹ̀, ẹ má jẹ́ kí ó lọ sinu ibojì,mo ti rí ìràpadà kan dípò rẹ̀.’

25. Jẹ́ kí àwọ̀ rẹ̀ jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde,kí agbára rẹ̀ sì pada dàbí ti ìgbà ọ̀dọ́;

26. nígbà náà eniyan óo gbadura sí Ọlọrun,Ọlọrun óo sì gbọ́ adura rẹ̀.Eniyan óo wá fi ayọ̀ wá siwaju Ọlọrun,yóo sì ròyìn ìgbàlà Ọlọrun fún gbogbo aráyé

Jobu 33