Jobu 28:24-27 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Nítorí pé ó ń wo gbogbo ayé,ó sì ń rí ohun gbogbo tí ó wà lábẹ́ ọ̀run.

25. Nígbà tí ó fún afẹ́fẹ́ ní agbára,tí ó sì ṣe ìdíwọ̀n omi,

26. nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,tí ó sì lànà fún mànàmáná.

27. Lẹ́yìn náà ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde,ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó sì dán an wò.

Jobu 28