21. Kì í jẹ àjẹṣẹ́kù,nítorí náà, ọlá rẹ̀ kò le tọ́jọ́.
22. Ninu ọlá ńlá rẹ̀ yóo wà ninu àhámọ́,ìbànújẹ́ yóo máa fi tagbára-tagbára bá a jà.
23. Dípò kí ó jẹun ní àjẹyó,ibinu ńlá ni Ọlọrun yóo rán sí i,tí yóo sì dà lé e lórí.
24. Bí ó bá ti ń sá fún idà,bẹ́ẹ̀ ni ọfà bàbà yóo gún un ní àgúnyọ-lódì-keji.
25. Bí ó bá fa ọfà jáde kúrò lára rẹ̀,tí ṣóńṣó orí ọfà jáde láti inú òróòro rẹ̀,ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá a.
26. Òkùnkùn biribiri ń dúró dè é,iná tí eniyan kò dá ni yóo jó o ní àjórun,ohun ìní tí ó kù ní ibùgbé rẹ̀ yóo sì parun.
27. Ọ̀run yóo fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn,ilẹ̀ yóo dojú ìjà kọ ọ́.