Jobu 17:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Níwọ̀n ìgbà tí o ti mú ọkàn wọn yigbì sí ìmọ̀,nítorí náà, o kò ní jẹ́ kí wọ́n borí.

5. Bí ẹnìkan bá hùwà ọ̀dàlẹ̀, tí ó ṣòfófó àwọn ọ̀rẹ́,kí ó lè pín ninu ohun ìní wọn,àwọn ọmọ olúwarẹ̀ yóo jìyà.

6. O ti sọ mí di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn eniyan,mo di ẹni tí à ń tutọ́ sí lára.

7. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,gbogbo ẹ̀yà ara mi dàbí òjìji.

8. Èyí ya àwọn olódodo lẹ́nu,aláìlẹ́bi sì dojú kọ ẹni tí kò mọ Ọlọrun.

9. Sibẹsibẹ olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i.

Jobu 17