Jeremaya 52:22-28 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ọpọ́n idẹ orí rẹ̀ ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati èso Pomegiranate yí ọpọ́n náà ká.

23. Òpó keji rí bákan náà pẹlu èso Pomegiranate. Mẹrindinlọgọrun-un ni àwọn èso Pomegiranate tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan; ọgọrun-un ni gbogbo èso Pomegiranate tí ó wà ní àyíká ẹ̀wọ̀n náà.

24. Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraaya, olórí alufaa ati Sefanaya tí ó jẹ́ igbákejì rẹ̀ ati àwọn aṣọ́nà mẹtẹẹta.

25. Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun, ati meje ninu àwọn aṣojú ọba tí wọn rí láàrin ìlú ati akọ̀wé olórí ogun tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀ fún ogun jíjà. Wọ́n tún kó ọgọta eniyan ninu àwọn ará ìlú tí wọn rí láàrin ìgboro.

26. Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó wọn lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila.

27. Ọba Babiloni sì pa wọ́n ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati.Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe kó àwọn eniyan Juda ní ìgbèkùn kúrò ní ilẹ̀ wọn.

28. Iye àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó lọ sí ìgbèkùn nìwọ̀nyí ní ọdún keje tí ó jọba, ó kó ẹgbẹẹdogun ó lé mẹtalelogun (3,023) lára àwọn Juu.

Jeremaya 52