5. Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ati Juda kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀;ṣugbọn ilẹ̀ Kalidea kún fún ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀,tí wọ́n dá sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.
6. Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni,kí olukuluku sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀!Ẹ má parun nítorí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ Babiloni;nítorí àkókò ẹ̀san OLUWA nìyí,yóo sì san ẹ̀san fún Babiloni.
7. Ife wúrà ni Babiloni jẹ́ lọ́wọ́ OLUWA,ó ń pa gbogbo ayé bí ọtí;àwọn orílẹ̀-èdè mu ninu ọtí rẹ̀,wọ́n sì ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.
8. Babiloni ṣubú lójijì, ó sì fọ́;ẹ sun ẹkún arò nítorí rẹ̀!Ẹ fi ìwọ̀ra pa á lára nítorí ìrora rẹ̀,bóyá ara rẹ̀ yóo yá.