28. Kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í,kí àwọn ọba ilẹ̀ Media múra, pẹlu àwọn gomina wọn,ati àwọn ẹmẹ̀wà wọn,ati gbogbo ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ wọn.
29. Jìnnìjìnnì bo gbogbo ilẹ̀ náà,wọ́n wà ninu ìrora,nítorí pé OLUWA kò yí ìpinnu rẹ̀ lórí Babiloni pada,láti sọ ilẹ̀ náà di ahoro,láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀ mọ́.
30. Àwọn ọmọ ogun Babiloni ti ṣíwọ́ ogun jíjà,wọ́n wà ní ibi ààbò wọn;àárẹ̀ ti mú wọn, wọ́n sì ti di obinrin.Àwọn ilé inú rẹ̀ ti ń jóná,àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ sì ti ṣẹ́.
31. Àwọn tí ń sáré ń pàdé ara wọn lọ́nà,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ikọ̀ ń pàdé ara wọn,bí wọ́n ti ń sáré lọ sọ fún ọba Babiloni pé ogun ti gba ìlú rẹ̀ patapata.
32. Wọ́n ti gba ibi ìsọdá odò,wọ́n ti dáná sun àwọn ibi ààbò,ìbẹ̀rùbojo sì ti mú àwọn ọmọ ogun.
33. Babiloni dàbí ibi ìpakà, tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ nígbà tí à ń pa ọkà.Láìpẹ́ ọ̀tá yóo dà á wó, yóo sì di àtẹ̀mọ́lẹ̀.Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
34. “Nebukadinesari ọba Babiloni ti run Jerusalẹmu,ó ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,ó ti sọ ọ́ di ohun èlò òfìfo,ó gbé e mì bí erinmi,ó ti kó gbogbo ohun àdídùn inú rẹ̀ jẹ ní àjẹrankùn,ó ti da ìyókù nù.