1. OLUWA bá wolii Jeremaya sọ̀rọ̀ nípa Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea pé:
2. “Kéde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ta àsíá, kí o sì kéde.Má fi ohunkohun pamọ́; sọ pé,‘Ogun tí kó Babiloni,ojú ti oriṣa Bẹli,oriṣa Merodaki wà ninu ìdààmú.Ojú ti àwọn ère rẹ̀, ìdààmú sì bá wọn.’
3. “Nítorí pé orílẹ̀-èdè kan láti ìhà àríwá ti gbógun tì í,yóo sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro,kò sì ní sí ẹni tí yóo gbé inú rẹ̀ mọ́,ati eniyan ati ẹranko, wọn óo sá kúrò níbẹ̀.