1. Máa sáré lọ, sáré bọ̀ ní àwọn òpópónà Jerusalẹmu,wò yíká, kí o sì ṣàkíyèsí rẹ̀!Wo àwọn gbàgede rẹ̀, bóyá o óo rí ẹnìkan,tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo,tí ó sì ń fẹ́ òtítọ́,tí mo fi lè torí rẹ̀ dáríjì Jerusalẹmu.
2. Lóòótọ́ ni wọ́n ń fi orúkọ mi búra pé, “Bí OLUWA tí ń bẹ,”sibẹ èké ni ìbúra wọn.
3. OLUWA, ṣebí òtítọ́ ni ò ń fẹ́?Ò ń nà wọ́n ní pàṣán, ṣugbọn kò dùn wọ́n,o tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́,ṣugbọn wọn kò gbọ́ ìbáwí.Ojú wọn ti dá, ó le koko,wọ́n kọ̀, wọn kò ronupiwada.