Jeremaya 48:40-47 BIBELI MIMỌ (BM)

40. OLUWA ní,“Wò ó, ẹnìkan yóo fò wá bí ẹyẹ idì,yóo sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ lé Moabu lórí.

41. Ogun yóo kó àwọn ìlú Moabu,wọn óo sì gba àwọn ibi ààbò rẹ̀.Ní ọjọ́ náà, ọkàn àwọn ọmọ ogun Moabu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ó ń rọbí,

42. Moabu yóo parun, kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́,nítorí pé ó ṣe ìgbéraga sí OLÚWA.

43. Ẹ̀yin ará Moabu,ìpayà, ọ̀gbun ati tàkúté ń bẹ níwájú yín!

44. Ẹni tí ó ń sálọ nítorí ìpayà,yóo jìn sinu ọ̀gbun,ẹni tí ó bá sì jáde ninu ọ̀gbunyóo kó sinu tàkúté.N óo mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá Moabunígbà tí àkókò ìjìyà rẹ̀ bá tó.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

45. Àwọn tí wọn ń sá fún ogun dúró ní ibi ààbò Heṣiboni,wọn kò lágbára mọ́,nítorí iná ṣẹ́ jáde láti Heṣiboniahọ́n iná sì yọ láàrin ilé Sihoni ọba;iná ti jó Moabu tíí ṣe adé àwọn ọmọ onídàrúdàpọ̀ ní àjórun,

46. Ẹ̀yin ará Moabu, ẹ gbé!Ó ti parí fun yín, ẹ̀yin ọmọ Kemoṣi,nítorí a ti kó àwọn ọmọkunrin yín lẹ́rú,a ti kó àwọn ọmọbinrin yín lọ sí ìgbèkùn.

47. “Sibẹsibẹ n óo dá ire Moabu pada lẹ́yìn ọ̀la,èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún Moabu.”

Jeremaya 48