Jeremaya 48:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. “Moabu ti parun; a gbọ́ igbe àwọn ọmọ rẹ̀.

5. Bí wọn tí ń gun òkè Luhiti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọkún,nítorí pé nígbà tí wọn tí ń lọ níbi ẹsẹ̀ òkè Horonaimu,ni wọ́n tí ń gbọ́ igbe ìparun; pé,

6. ‘Ẹ sá! Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín!Ẹ sáré bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aṣálẹ̀!’

7. “Ọwọ́ yóo tẹ ìwọ náà, Moabu, nítorí pé o gbójú lé ibi ààbò ati ọrọ̀ rẹ.Oriṣa Kemoṣi yóo lọ sí ìgbèkùn, pẹlu àwọn babalóòṣà ati àwọn ìjòyè rẹ̀.

8. Apanirun yóo wọ gbogbo ìlú,ìlú kankan kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀;àwọn àfonífojì yóo pòórá, a óo sì pa àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9. Ẹ bá Moabu wá ìyẹ́, nítorí yóo fò bí ẹyẹ;àwọn ìlú rẹ̀ yóo di ahoro, kò ní ku ẹnikẹ́ni ninu wọn.”

Jeremaya 48